Yoruba Learning Language

Yoruba Learning Language

Share

Eku dede iwo yi o eyin omo Yoruba oju ewe yi wa fun awon omo Yoruba ti kogbo ede Yoruba dara dara ni Oruko mini Ogbeni Yusuf Kamorudeen A.

Moje omo bibi Orilede Naijiria ni ipinle osun ni ijoba ibile isokan Apomu molosi ilewe alakobere ni ilu Apomu ADC primary 🎒🎒 🎒🏫🏫 School mote siwaju ninu eko mi molosi ile eko girama ADC gramar school ni odun 1983 mo rin irin ajo losi ilu Eko lati tesiwaju ninu eto eko mi molosi ile eko igba lode ti Emergency Comprehensive high school okokomaiko ojo ni ipinle Eko 🎒🎒🎒🎒🏫🏫🏫 motesiwaju ninu imo eko mi

13/01/2025

*OHUN MẸTA MẸTA TO ṢE KOKO NINU AYE ỌMỌ ENIYAN , TO YẸ KI A MA ṢE AKIYESI RẸ NINU AYE WA.*

*AGBỌDỌ NI AWỌN NKAN MẸTA WỌNYI.*
1. Otitọ
2 . Ìgbàgbọ
3 . Iwà Rere

*JA ARA RE GBA LỌWỌ NKAN MẸTA WỌNYI:*
1. Igberaga
2. Iyànjẹ
3. Gbese jijẹ

*AGBỌDỌ NI IKAPA LORI NKAN MẸTA WONYI:*
1. Ahọn
2. Ibìnù
3. Ife inu Ẹni

*YẸRA FUN NKAN MẸTA WỌNYI:*
1. Iwà Buburu
2. Biba Ọmọlàkejì jẹ lẹyìn.
3. Owu

*AGBỌDỌ NI NKAN META WONYI:*
1. Imọ
2. Iwà
3. If'okànsìn

*JẸ KI NKAN MẸTA WỌNYI WA NI MIMỌ TONITONI NI GBOGBO IGBA:*
1. Ara
2. Aṣọ
3. Ọkàn

*MA ṢE IRANTI NKAN MẸTA WỌNYI LOOREKOORE:*
1. Iku
2. Oore ti enìyàn
Ba Ṣe fun ọ
3. Amọràn Agbà

*Ẹ ṢE ÀTÚNṢE NI ONI KO TO DI WIPE OPE JU GBOGBO WA LA O SORIRE OOOO

11/11/2024

*🌺IṢẸ́ NI ÒGÚN `ṢÉ* *🖊️Múra sí iṣẹ́ Ọ̀rẹ́ mi* *🖊️Isẹ́ ni afí ń dẹni gíga* *🖊️Bí akò bá rẹ́ni fẹ̀yìntì* *🖊️Bí ọ̀lẹ là á rí* *🖊️Bí a kò bá rẹ́ni gbẹ́kẹ̀lé* *🖊️Á tẹra mọ́ isẹ́ ẹni* *🖊️Ìyá rẹ lè lówó lọ́wọ́* *🖊️Bàbá rẹ́ sì lè lẹ́shin lé kan* *🖊️Bí o bá gbójú lé wọn* *🖊️O tẹ́ tán ni mo sọ fún ọ* *🖊️Ohun tí a kò bá jìyà fún* *🖊️Ṣé kìí lè tọ́jọ́ rárá* *🖊️Ohun tí a bá fara ṣiṣẹ́ fún* *🖊️Ní npẹ́ lọ́wọ́ ẹni* *🖊️Apá lará* *🖊️Ìgúpá nì ìyè kàn* *🖊️Bí aiyé bá ńfẹ ọ lónìí* *🖊️Tí o bá lówó lọ́wọ́* *🖊️Ayé á máa fẹ́ ọ lọ́lá* *🖊️Jẹ́kí o wà ní ipò àtàtà* *🖊️Aiyé á ma yẹ́ ọ sí tẹ̀rín-tẹ̀rín* *🖊️Jẹ́kí ó dẹni tí ń ràgò* *🖊️Kó o rí bí aiyé tí n yínmú sí ọ* *🖊️Ẹ̀kọ́ sì lè ṣẹni dọ̀gá* *🖊️Múra kí o kọ dáradára* *🖊️Bí o rí ọ̀pọ́ ènìyàn* *🖊️Tí ń fi ẹ̀kọ́ ṣẹ̀ rín rín* *🖊️Dákun má fara wé wọn* *🖊️Ìyà ńbọ̀ fọ́mọ tí kò gbọ́n* *🖊️Ẹkún ń bẹ fọ́mọ tí ó ń sá kiri* *🖊️Má fòwúrọ̀ ṣeré ọ̀rẹ́ mi* *🖊️Múra sí iṣẹ́ ọjọ́ ń lọ. Can you still remember the Poem , in pry School.*👌🏼👍🏼

THESE ARE MISSING NOWADAYS.

Want your public figure to be the top-listed Public Figure in Ojo?
Click here to claim your Sponsored Listing.

Category

Telephone

Website

Address

Igbo Elerin Road
Ojo
102101